ÌJÚBÀ (PAYING HOMAGE)

Ìbà Olódùmarè

Ìbà ilẹ̀

Ìbà àtiwáyé ọjọ́

Ìbà àtiwọ̀ oòrùn

Ìbà áríwá

Ìbà Gúsù

Ìbà Egúngún 

Ìbà Òrìṣà 

Ìbà Bàbá mi (orúkọ Baba) 

Ìbà Yèyé mi (orúkọ ìyá)

Ìbà Olúwo mi (orúkọ Olúwo)

Ìbà Ojugbona (orúkọ Ojugbona)

Ìbà Ìyánífá mi (orúkọ Iyanifa)

Ìbà àwọn Apẹ̀tẹ̀bí aya Ọ̀rúnmìlà 

Ìbà Àjàgùnmọ̀lè, Olúwo òde Ọ̀run

Ìbà Àrànìsàn, Olúwo òde Ọ̀run

Ìbà àhànnàmọ̀jà tí kọ́ ọmọ nífá ojú àlá

Ìbà Àràbà Baba Eríwo 

Ìbà párìpá adáṣọ má mú ró

Ìwérénjéje, párákùn Ọbàrìṣà

Àfi bí mo dá ṣe 

Kórò má ṣàìgbà 

Bàbá bá mi ṣe é 

Àṣefín, àṣegbà

Ìyá bá mi ṣe e

Àṣefín, àṣegbà

Orí bá mi ṣe e

Àṣefín, àṣegbà

Ikin bá mi ṣe e

Àṣefín, àṣegbà

 

 

Homage to Olodumare

Homage to Ile, the Mother Earth

Homage to the East

Homage to the West

Homage to the North

Homage to the South

Homage to the Ancestors

Homage to the Deities

Homage to my father (name of the father)

Homage to my mother (name of the mother)

Homage to my Oluwo (name of the Oluwo)

Homage to my Ojugbona (name of the Ojugbona)

Homage to my Iyanifa (name of the Iyanifa)

Homage to all the Apetebi, wives of Orunmila

Homage to Ajagunmale, a chief priest in the Spiritual realm

Homage to Aranisan, a chief priest in the spiritual realm

Homage to Ahannamoja, who teaches one Ifa in dream

Homage to Araba, the most high chief priest

Home to Paripa, who has cloths but walks naked

Here is Iwerenjeje, a plant of Obarisa

Unless I do without paying homage

My undertakings should never be fruitless

My father, help me do it 

Do it in a meticulous way that yields favourable results

My mother, help me do it 

Do it in a meticulous way that yields favourable results

My Ori, help me do it 

Do it in a meticulous way that yields favourable results

My Ikin, help me do it 

Do it in a meticulous way that yields favourable results